Subscribe Us

header ads

Omi Iye Naa (CAC Living Water) - Mase Wipe 'ko Le Seese Nisinsin Yii (1)

Omi Iye Naa (CAC Living Water) 18th October 2021 - Mase Wipe 'ko Le Seese Nisinsin Yii (1)

Omi Iye Naa (CAC Living Water) 18th October 2021 - Mase Wipe 'ko Le Seese Nisinsin Yii (1)

Akori: Mase Wipe 'ko Le Seese Nisinsin Yii (1)

Ka Danieli 6:1-5, 10-16

Akosori: Nigba naa ni awon okunrin wonyii wi pe, awa ki yoo le ri esun kan si Danieli bikose pe a ba ri I si I nipase ofin Olorun re (Danieli 6:5)

ITUPALE

O to lati soro nipa jije mimo nipa Ibalopo ati titona dagba ni ona ti o ye ni awon ile ajeji. E je ki a soro nipa ilowosi ninu ise ijoba ati iselu ni ile ajeji tabi ibugbe to jina si ile eni gan! Danieli ni koko itokasi wa.

Danieli ati awon ore re Heberu meta je ara awon omodekunrin, koda lati idile oba ti won ba ara won ni Babiloni (Igbekun), sugbon ti a mu won wonu sise ise fun oba ni ona iyanu ati pelu eto atorunwa. Ipa ati okiki omodekunrin eru yii n po gidigidi debi pe oba fi I se olori awon olori. Eyi gan-an ni o sokunfa owu jije ati ikorira lati odo awon yooku ti won ko le so/tokasi orisun aseyori ati idide re, eredi ti won fi gbimo po lati fi mu un niyii. Won fe da a lekun lati mase sin Yahweh mo, eni tii se Orisun agbara/okun re.

Oro awon ota wonyii nipa Danieli lenu ise (ese 5, wo Owe 22:1) ijoba ni ile ajeji to lati gboriyin fun. Nje a le so eyi nipa re nibikibi ti o ti gbe ri tabi ti o n gbe, paapaa julo laarin awon ti kii se omo ilu re? Gbogbo won ni won wa lenu ise oba, sugbon awon olote wonyii salaini ohun ti Danieli ni - otito inu. Danieli je eni ti a fi idi otito re mule ni ile ti o ti le se pe ko le seese.

Opo ninu ww maa n so pe osunwon Olorun fun wiwa ni ibi ise ijoba tabi ninu iselu ko le seese pelu won, bii pe Olorun ko ni won lokan nigba ti O n se ikeee ofin naa. Ko si ohunkohun ti o gbodo mu o gbojege osuwon otito ti Olorun reti lati odo re ni ibi ise yen. Mase so pe, "Bi N ko ba le segun won, N o darapo mo won" (Eks. 23:2). Ohunkohun ti Olorun ba so ninu Oro Re ni a ko gbodo ri bi eru/ajaga, sa a gboran si I lenu.

AWON KOKO ADURA:

1. Oluwa, mu mi je Danieli Iran yii, ti o setan lati duro fun otito Re, laiwo ti idibaje to ti gba aye isinsin yii kan.

2. Mo ko oati gbojege igbagbo ati otito mi ninu Re Oluwa, ni oruko Jesu.

3. Oluwa, fi iyanu gbe awon Danieli ati Kirusi dide sii ti yoo duro fun O ninu eto iselu orile-ede wa, ni oruko Jesu.

AFIKUN IBI KIKA FUN ONI: Isaiah 39:8 - 42-2; Kolose 3:8-4:4.

Post a Comment

0 Comments