Subscribe Us

header ads

Aigbagbo Bila - Yoruba Hymn

Aigbagbo Bila - Yoruba Hymn

Aigbagbo bila! Temi l'Oluwa
Oun o si dide fun igbala mi,
Ki n sa ma gbadura, Oun o se 'ranwo:
'Gba Krist' wa lodo mi, ifoya ko si.

Bona mi ba su, Oun l'O sa n to mi,
Ki n sa gboran sa, Oun o si pese;
Biranlowo eda gbogbo ba saki,
Oro tenu Re so yo bori dandan.


Ife to n fi han, ko je ki n ro pe,
Yo fi mi sile ninu wahala;
Iranwo ti mo si n ri lojojumo,
O n ki mi laya pe emi o la a ja.

Emi o se kun tori iponju,
Tabi irora? O ti so tele!
Mo moro Re pawon ajogun 'gbala,
Wo ko le sai koja larin wahala.


Eda ko le so kikoro ago
T'Olugbala mu kelese le ye;
Aye Re tile buru ju temi lo,
Jesu ha le jiya, kemi si ma sa.

Nje bohun gbogbo ti n sise ire,
Adun nikoro, ounje li oogun;
Boni tile koro, sa ko ni pe mo,
Gbana orin 'segun yio ti dun to!

Watch Video Below


The copyrights of these songs/hymns do not belong to thechristianfeed.net. Enjoy and share.

Post a Comment

1 Comments