Subscribe Us

header ads

Ẹ̀kọ́ Ilẹ̀ Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi [CAC Sunday School 21st November 2021]

Ẹ̀kọ́ Ilẹ̀ Ẹkọ́ Ọjọ́ Ìsinmi Ìjọ Àpọ́sítélì Kristi [CAC Sunday School Lesson 21st November 2021]

Ẹ̀kọ́ Ilẹ̀ Ẹkọ́ Ọjọ́ Ìsinmi Ìjọ Àpọ́sítélì Kristi [CAC Sunday School Lesson 21st November 2021]
Àkòrí Gbòòrò: Ní Irú Àkókò Bí Èyí

Ìsọri Kẹta: Fífọ/Pinpin Si Yẹlẹyẹlẹ Nínú Eto Ìdílé

Ọjọ: November 21st 2021

Àkòrí: Àwọn Ipenija To Ní Ṣe Pẹ̀lú Ìdílé Ìpín Kejì

ÌDÍLÉ BẸ̀RẸ̀ SII KOJU IPENIJA (Gẹnesisi 3:1; 16:1swj; 29:14b-30; 37:12-36; 1 SAMUELI 2:12swj; 1 Kọ́ríńtì 3:3; 10:13; Éfésù 4:1swj; 5:22-33; Hébérù 13:4).

Àwọn àkókò tí nnkan dán mọran àti ìgbà tí nnkan ko rọgbọ a máa wa ninu gbogbo ìdílé, ibaṣepọ inú ìdílé ni a le gbádùn, bí àwọn ènìyàn ìdílé ba fi ọwọ sowọpọ pẹ̀lú Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá àti Olùdarí ìdílé.

A. ÀWỌN OKÙNFÀ RẸ (Gen. 3:1; 16:1swj; 29:14b-30; 37:12-36; 1 Sam. 2:12swj; 10:13)




Nítorí ẹyin jẹ ti ara síbẹ̀ nítorí níwọ̀n bí ìlara àti iyapa ba wa láàrin yin, ẹyin ko ha jẹ ti ara, ẹ ko ha sin n rin gẹ́gẹ́ bí ènìyàn? (I Kor. 3:3).

i. Kosi ibaṣepọ àti ìgbéyàwó pẹ̀lú, ó í o bọ lọ́wọ́ ipenija (wo I Kor. 10:13). Ọlọ́run nínú gíga julọ Rẹ faaye gba àwọn ipenija kan láti wáyé/ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé, ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, o máa ń yọrisi ogo Rẹ ati ìbùkún fún àwọn ìdílé tí o dojúkọ ipenija náà (Amosi 3:6; Rom. 8:28).

ii. I Kor. 3:3: Ọ̀pọ̀ ipenija ìdílé máa ń wáyé nígbàkúùgbà tí a ba ti sọtẹ/ṣelodi si ojúlówó, ifẹ eto ati àwọn ìtọ́ni Ọlọ́run. Sátánì ni okùnfà rẹ (I Pet. 5:8). Ìjà laarin ìdílé, ipaniyan, iwa aitọ tí ibalopọ laarin ìdílé abbl ni yóò tẹle iṣẹlẹ̀ búburú ìṣubú ènìyàn, ní Gen. 3.

iii. Ìgbéyàwó/ìdílé yòówù tí a ba gbe le ipilẹ miran ti ó yàtọ̀ si Kristi àti ìwà-mimọ Rẹ ko le ṣai dojúkọ àwọn iji ayé loorekoore (Orin Daf. 11:3; wo Mat. 7:24).

iv. Gen. 3:1: Nibo ni Ádámù wa nígbà tí satani ń bá Éfà sọ̀rọ̀? Jíjìnnà sì ara ẹni àti iyapa tí ko nitúmọ̀ jẹ àwọn ohun to ń ṣokùnfà àwọn ipenija gan-an nínú ìgbéyàwó. Ko si awawi fun iyapa tí a le yẹra fún ati jíjìnnà síra fún ìgbà pipẹ tàbí iyapa ni ọna miran láàrin ọkọ àti ìyàwó.

v. 16:1swj: Idaduro nípa ti ọmọ bibi lè fa àwọn ipenija kan nínú ìdílé. O mú kí Sara o fún ọkọ rẹ ni ìmọ̀ràn tí o lòdì. O ṣokùnfà ede aiyede ni ìdílé Ẹlikénà (I Sam. 1:1swj).

vi. 29:14-30: Ikayajọ jẹ okùnfà miran. Igbe ayé ẹni tó bẹ̀rẹ̀ rẹ kì ṣe ohun to wuni rárá (4:19swj). O máa ń mú kí ìlara, ifagagbaga, ṣíṣe orogun, idaduro àti nígbà míràn, ikú o ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé. O dara ki a yẹra fún un bii ajakalẹ àrùn.

vii. 37:12-36: Irúgbìn ikorira/ìkorò to mú kí àwọn arákùnrin Jósẹ́fù o ta a (wo Efe. 4:31; Heb. 12:15).

iii. I Sam. 2:12swj: Àwọn ọmọ oniwahala le jẹ àbájáde aikunju oṣunwọn obi. O le yọrí sí ìṣòro ńlá ni àwọn ìdílé kan; abamọ àti ikú Eli, bí ìtọ́kasi. Ábúsálómù le baba rẹ, Ọba Dáfídì kúrò lórí ìtẹ́.

ix. Iku àwọn ẹni tí a fẹ́ràn --- Ọkọ̀/aya, ọmọ abbl, le yọrisi ìṣòro ńlá nínú ìdílé. Fún àpẹẹrẹ, àwọn opo máa n la ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipenija kọjá láti gbọ bukata àwọn ọmọ wọn (2 A. Ọba 4:1-8).

x. Ju gbogbo rẹ lọ, nígbà tí ko ba si ìfẹ́ tòótọ́ (ìfẹ́ afẹtan) nínú ìdílé àwọn ipenija àti ìṣòro tí a ko le yẹra fún yóò máa bẹ ìdílé náà wò loorekoore (Efe 5:22swj).

B. ỌNA ÀBÁYỌ (Éfésù 4:1swj; 5:22-23; Heb. 13:4).

Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yín kí o fẹ́ràn aya rẹ bẹẹ gẹ́gẹ́ bí òun tìkárarẹ, kí ara kí o si bẹru ọkọ rẹ (Éfésù 5:33).

i. Efe. 5:31-32: Kọ ilé náà sórí ipilẹ didaju àti ìwà-mimọ Kristi (Orin Daf. 11:3; Mat. 7:24swj). Kẹ́kọ̀ọ́ lára Isaaki àti Rèbékà (Gen. 24:1swj).

ii. Ẹsẹ 22swj: Ìfẹ́, ifẹ tòótọ́ (Ifẹ̀ afẹtan/onirubọ) gbọ́dọ̀ jẹ ipilẹ àti ohun to ń rú àwọn mọlẹbi ìdílé sókè:-

* Ifẹ̀ ìyàwó gbọ́dọ̀ jẹ ìfẹ́ tòótọ́, o gbọ́dọ̀ ni ìtẹríba pátápátá àti láìsí títóri) (ẹsẹ 22-24).

* Ifẹ̀ ọkọ gbọ́dọ̀ jẹ ìfẹ́ tòótọ́, ó gbọ́dọ̀ jẹ ónìrúbọ (ìfẹ́ pátápátá àti láìsí tìtorí) (ẹsẹ 25-30) àti

* Ifẹ̀ àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ jẹ ìfẹ́ tòótọ́, ifẹ pátápátá, kí wọ́n sì gbọ́ràn láìsí tìtorí) ẹsẹ 6:1-3), gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí wọn náà tí ń bẹbẹ fún ìranlọwọ Ọlọ́run láti kọ/tọ wọn nínú Olúwa láìsí inúnibíni.

iii. Heb. 13:4: A gbọ́dọ̀ mú odiwọn ìwà-mimọ lọkunkundun nínú ìdílé kí a ba le maa jẹgbadun ojurere Ọlọ́run ni gbogbo ọjọ ayé wa.

iv. Efe 4:1: A gbọ́dọ̀ fọwọ́ dídára mú ìṣọ̀kan. Ní ìṣọ̀kan ni a dúró... Gbogbo ara ile/ìdílé gbọ́dọ̀ fi ara wọn jì ni ṣíṣe ohun gbogbo láti mú ìṣọ̀kan dúró nínú ìdílé, ko gbọ́dọ̀ si imọtara-ẹni-nìkan, ko si gbọ́dọ̀ si ogo asán.

v. Gbogbo ara/ìdílé gbọ́dọ̀ kọ ìlànà jíjà láti rẹ/dọrẹ. Ìjà ko gbọ́dọ̀ tú wọn ka. Nítorí náà, ẹ yẹra fún ìkorò ọkàn àti ikorira (Mat. 5:21-25; Efe. 4:26; Kol. 3:13).

vi. Nígbà tí ìdílé bá ń la ipenija kankan kọjá, àwọn ara ile/ìdílé gbọ́dọ̀ rí i gẹ́gẹ́ bí ọna ti Ọlọ́run ń gba láti fi ògo fún araRẹ (Rom. 8:28; wo Jhn. 9:1-5); ko gbọ́dọ̀ sí dídì ẹbi ru ẹnikẹ́ni.

vii. Ju gbogbo rẹ lọ, fifi ọkàn si ọrun, èyí tí kíkún fún Ẹ̀mí-Mímọ́ yóò rán gbogbo ìdílé lọ́wọ́ láti ni àfojúsùn kan náà --- ògo Ọlọ́run --- èyí tí yóò yọrisi yiyẹra fún ìgbọ́kànsoke tí ko nitúmọ̀ àti bibori gbogbo ipenija papọ (Kol. 3:1swj).

viii.Lati le sọ ìdílé rẹ di ibùgbé ayọ tí Ọlọ́run, a ń retí kí o yí ojú ìwòye rẹ, èrò rẹ padà, èrò ọkàn rẹ gbọ́dọ̀ ba ti Ọlọ́run mú, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ sínú ọrọ Rẹ; lai si abula, láìsí ilọ lọrun.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ́

1. Lai fi Ọlọ́run àti ìwà-mímọ Rẹ ṣe ohun àkọ́kọ́ nínú, gbígbé-igbesẹ wọnú ìgbéyàwó àti ìdílé, gbogbo igbiyanju yóò kùnà.

2. Jẹ olufẹ àlàáfíà, Ifẹ̀, ìṣọ̀kan àti ìtẹsiwaju. Máa ṣàfẹ́rí àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará ilé rẹ kì o si ri bí Ọlọ́run tí ń mú gbogbo yín lọ si ipele gíga eto Rẹ fún ìdílé rẹ.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ

1. Ìdílé jẹ Idasilẹ Ọlọ́run, kin ni èyí túmọ̀ si, si ìwọ àti ibaṣepọ ìdílé rẹ?

2. Ǹjẹ́ a le mú ìdílé to tí tuka/yapa bọsipo si? Ṣàlàyé.

ÀWỌN ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ :

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ I:

i. Ìdílé jẹ igbekalẹ Ọlọ́run. Ọlọ́run gbé ìdílé kalẹ; O bẹ̀rẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. Ọlọ́run da Ádámù Ó si mú Éfà (obinrin naa) jáde láti inú egungun tí O yọ láti ìhà ọkùnrin náà láti wa oluranlọwọ tí o da bi ọkùnrin náà (Ádámù) fún un. Ìdílé ni Ọlọ́run gbé kalẹ láti ṣe ìmúṣẹ erongba àti eto Rẹ.

ii. Kín ni èyí túmọ̀ si fún ìwọ àti ibaṣepọ ìdílé Rẹ?

iii. Ọlọ́run, Orísun ìdílé túmọ̀ si:

* Ọlọ́run ṣẹda ìdílé, Òun ni a si gbọ́dọ̀ rí gẹ́gẹ́ bí Orí àti Alákóso.

* Ìdílé no Ọlọ́run gbé kalẹ fún eto ara Rẹ.

* Ìdílé ni a gbé kalẹ fún ibakẹgbẹ pọ, ifẹ̀ àti ìṣọ̀kan láàrin àwọn ènìyàn ìdílé náà.

* Ọlọ́run, oludasilẹ ìdílé tàbí ilé, ní a gbọ́dọ̀ fún ní apọnle àti idamọ nínú ìdílé tàbí ilé wa.

* Ìdílé ni ko le e ṣe àṣeyọrí laigba ìtọ́ni Ọlọ́run, ọrọ, ìdarí àti òfin Rẹ gbọ.

* Ìdílé ni a da láti inú ìfẹ́ Ọlọ́run. Nítorí náà, ọna kan ṣoṣo tí ìdílé fi lè ṣe déédéé gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run (Oludasilẹ) ṣe ń fẹ́, ní pe ki wọn ní ìfẹ́ tòótọ́ àti tọkàntọkàn sì ara wọn nínú ẹbi.

iv. Níni ibaṣepọ tí ìdílé, a gbọ́dọ̀ rí Ọlọ́run ní àwọn ọ̀nà wọnyii:

* Ìfẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ hàn nínú ifarada àti ìfara-ẹni-ji àìmọ tí ara ẹni nìkan (I Kor. 13:1swj)

* Ibara ẹni sọ̀rọ̀ tí o dán mọran láàrin àwọn ènìyàn ìdílé paapaa àwọn tọkọtaya.

* Ṣíṣe iranlọwọ fún ẹnikẹ́ni nípa ti ara, tí ẹmi, nípa owo, nínú ibaṣepọ, ní ero ọkàn, ọrọ aje, abbl.

* Ifaraji fún Ọlọ́run àti isin/ìṣẹ́ Rẹ.

* Kíkọ àwọn ọmọ ni ọna Ọlọ́run (Òwe 22:6).

* Kí a máṣe da ara wa lẹjọ, ṣùgbọ́n ki a maa gbe papọ, ko da nínú wàhálà tàbí ìjì.

* Didari jí ara wa nígbà gbogbo (Oniw. 7:9; I Jhn. 3:21).

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ 2

i. Bẹ́ẹ̀ ni! Ilé tí o ti tuka ni a le mú padà bọ sípò. Ko si ohun ti ó ṣòro fún Ọlọ́run láti ṣe, Oun ni idi ti ìdílé fi wa, O si korira ikọsilẹ.

ii. Ọlọ́run kò le e jẹ ẹlẹ́ri níbi ìgbéyàwó tọkọtaya kan kí o sì tún jẹ́ ẹlẹ́rìí sí iyapa wọn (Mal. 2:14-16). Kí a ma rí!

iii. Àwọn lọkọlaya gbọ́dọ̀ ni lọ́kàn pé:

* Ọlọ́run korira ikọsilẹ (Mal. 2:16a)

* O kún fún ìnira, ìrora, abamọ, abbl. (Òwe 17:22)

* A máa da apá sì ara àwọn tọkọtaya pẹ̀lú ìrora lára àwọn ọmọ wọn àti ìran tí ń bọ̀. Ṣọ́ra!

iv. Lẹ́yìn tí a ti ṣe agbeyẹwo àwọn tí òkè wọnyii, ilé tí o dàrú ni a lè mú padà bọsipo nípa bayii:

* Àwọn tọkọtaya tí gbọ́dọ̀ gba Jésù ni Oluwa àti Olùgbàlà wọn tọkàntọkàn-ìrònúpìwàdà ojúlówó.

* Àwọn tọkọtaya gbọ́dọ̀ wa ojú Ọlọ́run fún ìdáríjì kí wọn sì nífẹ̀ẹ́ sí imupada bọ sípò (1 Jhn. 3:22).

* Wọn gbọ́dọ̀ wa ẹni ìwà bí Ọlọ́run ti o si ni ìrírí fún ìtọ́ni. Irú ẹni bẹẹ lee jẹ ìránṣẹ́ Ọlọ́run.

* Ṣe tán láti darí jí ara rẹ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe sí àwọn ọ̀tá Rẹ. Bí o ba kọ láti dárí jì, gbàgbé nípa ìjọba Ọlọ́run (2 Kor. 2:5-11; Jak. 1:21).

* Ní ọkàn bí Ọlọ́run láti gbàgbé àwọn ẹṣẹ àtẹ̀yìnwá, ìyàn jíjà tàbí ìdálẹ́bi gbogbo.

* Ṣe ohun gbogbo láti mú ìdílé náà padà kí o si mọ dájú pé ìwọ yóò jíhìn nípa ìdílé yẹn ni ọjọ́ ìdájọ́.

* Mú ìdílé yẹn padà nítorí Ọlọ́run àti ìjọba Rẹ.

* Gbàdúrà fún ọkọ tàbí aya rẹ, ilé àti ìwọ fúnra rẹ (1 Jhn. 5:14).

* Fi ọkàn ọkọ tàbí aya rẹ lè Ọlọ́run lọ́wọ́.

* Gbagbọ kí o si ni igbagbọ nínú Ọlọ́run ìdílé.

* Jẹ ki ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa tọ ọ (Heb. 12:14)

* Dẹkùn igbiyanju lati borí ìyàn jíjà ṣùgbọ́n máa fi ara mọ pe kò sì ọta bẹẹ ni ko si ope.

* Inú rẹ yóò dùn pé o gbé irú igbesẹ bẹẹ àti pé inú Ọlọ́run yóò dùn pẹ̀lú.

ÀMÚLÒ FÚN IGBE AYÉ Ẹ̀NI:

Tọkọtaya kan wa nígbà kan rí tí ìyàn jíjà pẹ̀lú àìgbọràn ẹniye wọn yọrí sí ikọsilẹ lẹ́yìn o rẹyìn. Kí wọn to yapa fún ara wọn, ọkọ dunkoko mọ obìnrin láti fi ilé náà silẹ pẹ̀lú ọmọ mẹta, ṣùgbọ́n obìnrin náà wí pé òun ti jẹjẹẹ láti igbe èwe òun wa pé òun ko ni kúrò ní ilé ọkọ òun nítorí ìdí yowu. Ní ọjọ́ kan, ọkùnrin náà yọ gbogbo fèrèsé àti ilẹkun ilé láti lè jẹ ki obinrin naa jáde, ṣùgbọ́n ko lọ. O tún lo àwọn ọ̀nà miran láti dẹru ba a kì o le jáde kí ìyàwó tuntun lè ko ẹrú wọ ilé, síbẹ̀ pàbó ni o ja si.

Ni ọjọ́ kan, ọkọ yii mu ọbẹ̀ wá láti fi gún obinrin naa pa, ṣùgbọ́n àwọn aladugbo tètè da sii. Obìnrin náà sì fi ilé náà silẹ. Ǹjẹ́ Ọlọ́run lè gbà irú nnkan bayii láàyè lai da sii bi?

Ọlọ́run, nínú títóbi Rẹ, fihan pe Oun nìkan ni O ni ìdílé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn ikọsilẹ, Ọlọ́run pàṣẹ fún ọkùnrin náà láti wa ìyàwó tí o ti kọ sílẹ̀ lọ kí o si mú ú padà wa sílè, bí o ba n fẹ́ àlàáfíà èyí tí o ti fi sílẹ̀ lọ gidigidi náà fi ayọ padà sí ilé rẹ, ìgbéyàwó náà ni a mú padà bọsipo sí ìdùnnú àwọn ọmọ tí wọn tí ṣáko lọ nígbà kan rí.

Ṣe ohun gbogbo tí o ba le e ṣe láti ni ìwà láàyè Ọlọ́run, ifẹ, àlàáfíà àti oore ọ̀fẹ́ nínú ilé rẹ. Ọlọ́run ko lee fi ọwọ sì iyapa tàbí ikọsilẹ fún àwọn ìdí yowu.

IGUNLẸ

Inú Ọlọ́run ko dùn sí àwọn ìdílé tí wọn kọ láti fi ọwọ sowọpọ pẹ̀lú Rẹ láti mú eredi tí o fi mú wọn papọ gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti aya, àti gẹ́gẹ́ bí òbí àwọn ọmọ ṣẹ. A gbọ́dọ̀ sa fún ìbínú Ọlọ́run, nípa ṣíṣe ohun gbogbo tí ó ba ṣe e ṣe láti, dáàbò bo faya rán jẹgbadun àti fi fọwọsowọ́pọ̀ nínú ètò Ọlọ́run.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KEJI

Mon. 15: Ipilẹ Gbọ́dọ̀ Dúró Lórí Jésù (Mat. 7:24-27)

Tue.   16: Àwọn Ìdílé Tí Wọn Jẹ Olotitọ Ṣi Ń Koju Ipenija (Luk. 1:5-21)

Wed.  17: Jíjẹ Olotitọ Si Ara Wọn Rán Wọn Lọwọ (Luk. 1:22-25)

Thur.  18: Àgbèrè Lè Ṣekunpani (A. Onid. 16:16-31).

Fri.      19: Tẹle Àpẹẹrẹ Ìjọ Kristi (Efe. 5:22-33).

Sat.     20: Ipenija Ìdílé Kii Ṣe Òpin Rẹ (I Kor. 10:13).

Post a Comment

0 Comments