Subscribe Us

header ads

Ẹ̀kọ́ Ilẹ̀ Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi [CAC Sunday School 14th November 2021]

Ẹ̀kọ́ Ilẹ̀ Ẹkọ́ Ọjọ́ Ìsinmi Ìjọ Àpọ́sítélì Kristi [CAC Sunday School Lesson 14th November 2021]

Ẹ̀kọ́ Ilẹ̀ Ẹkọ́ Ọjọ́ Ìsinmi Ìjọ Àpọ́sítélì Kristi [CAC Sunday School Lesson 14th November 2021]

Àkòrí Gbòòrò: Ní Irú Àkókò Bí Èyí

Ìsọri Kẹta

Fífọ/Pínpín Si Yẹlẹyẹlẹ Nínú Ètò Ìdílé

Ọjọ: November 14 Àti 21, 2021

Ẹ̀kọ́: Kẹsàn-án

Àkòrí: Àwọn Ipenija To Ni I Ṣe Pẹ̀lú Ìdílé

Akọsori

Ṣùgbọ́n ọkùnrin ko le ṣe láìsí obìnrin, bẹẹ ni obìnrin ko le ṣe láìsí ọkùnrin nínú Olúwa. (I Kọ́ríńtì 11:11).

Ọlọ́run da ènìyàn O fi si inu ọgbà dáradára, Ó si fún un ní oluranlọ́wọ́, sátánì tí inú rẹ ko dùn da eto naa ru, èyí ni eredi onírúurú àwọn ipenija ìdílé tí a ní lonii. Máṣe jẹ ki sátánì ó fọwọ́ ba ìdílé/ilé rẹ!

ÀLÀYÉ KÚKÚRÚ

Ọlọ́run nínú ètò Rẹ láti orun wa, da ènìyàn, àti láti inú ọkùnrin náà (Ádámù), O mú egungun iha èyí tí O lo láti fi ṣe oluranlọwọ (Éfà), fún ọkùnrin náà.

Eto ati igbekalẹ Ọlọ́run ni o pe ti o si wa títí láé. Nípasẹ̀ eto Ọlọ́run láti òkè wa, ọkùnrin àti obìnrin náà ní a ń retí kí wọn jọ maa gbe papọ láìsí iyapa, bí o ti wu ki o ri, ipenija, ìjì, tàbí ipokipo tí wọn iba a wa. Nígbà tí ẹnikinni ba ri ọkọ tàbí ìyàwó rẹ gẹ́gẹ́ bí oluranlọ́wọ́ pátápátá tàbí alati lẹyin láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti mú erongba, eto, tàbí èrò ọkàn wọn ṣẹ, ibaṣepọ a máa rọrun si i. Èṣù (sátánì), tí o jẹ ọta Ọlọ́run títí láé, ní o n ṣe ohun gbogbo láti pa eredi ti Ọlọ́run fi gbé ìdílé kalẹ run. Eyi ni ó ń ṣe nípa didojukọ ìdílé nípasẹ̀ onírúurú ipenija, bii ìjì, àìgbọra-ẹni-ye, ìbínú, ìjà, ìṣòro owo, airọmọ bi, ikorira, ikọsilẹ, àìsí ìṣọ̀kan, abbl. Nígbà tí a ba dẹkùn rírí ọkọ tàbí aya gẹ́gẹ́ bí orísun ìṣòro yowu nínú ilé, èyí yóò rán wa lọ́wọ́ láti fi ọwọ sowopọ nínú ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ìdílé láti já kí a si ṣẹgun gbogbo ìṣòro tí o le koko àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ko dara tí wọn ń gbógun ti ìdílé wa.

ÀṢÀRÒ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ FÚN ỌSẸ KÍNNÍ

Mon. 8: Ọlọ́run Ṣàgbékalẹ ìgbéyàwó Àti Ìdílé (Gen. 2:18, 20-21)

Tue.   9: Àìsí Iwa-Bí-Ọlọ́run Ní O N Ṣokùnfà Ìjà Nínú Ìdílé (Gen. 4:1-7)

Wed. 10: Ọmọkùnrin Alaiwa-Bí-Ọlọ́run Ju Ìdílé Sínú Iṣọfọ (Gen. 4:8-16)

Thur. 11: Lámékì Alaiwa-Bí-Ọlọ́run Ẹni To Bẹ̀rẹ̀ Ikayajọ (Gen. 4:19-24)

Fri.     12: Ọlọ́run Fi Ṣeti Fún Gẹ́gẹ́bí Ìtùnú (Gen. 4:25-26)

Sat.    13: Lori Ifẹ̀ Kristi Ní A Ń Kọ/Gbé Ìdílé Oníwà-Bí-Ọlọ́run Le (Efe. 5:22-23)

ÀṢÀRÒ FÚN ÌFỌKÀNSÌN




1. Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ pèsè fún àṣeyọrí ìdílé. A máa n ní ìrírí ijakulẹ nígbà tí a ba kùnà láti tẹle E.

2. Ìgbéyàwó kí ìṣe kí a wa nínú ìfẹ́; kí a sì gbadun ara wa nìkan, ṣùgbọ́n bí a ba fi ojú iwa mimọ wo o, Ọlọ́run ni eredi àti eto ti o tobi fún un.

ẸSẸ BÍBÉLÌ FÚN IPILẸ Ẹ̀KỌ́ : Romu 15:1-7

ILEPA ÀTI ÀWỌN ERONGBA ILEPA: Láti ran wa lọ́wọ́ láti ṣe àwárí pé dandan ni ipenija nínú ìgbéyàwó tàbí ìdílé, kí a si lè tọ́kasi bí a ṣe le dojú kọ ipò bẹẹ lai ba ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run jẹ.

ÀWỌN ERONGBA: Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ yii, akẹ́kọ̀ọ́ yóò le:

i. Ṣé àfihàn àwọn ẹri anikun imọ pé ìdílé ni a gbé kalẹ tí a si n tọpinpin rẹ láti ọwọ Ọlọ́run tako gbogbo wàhálà àti ìlòdì sí.

ii. Fihan pe àwọn ipenija tí o n koju àwọn ìdílé wa lati ro wọn ní agbára àti láti ro ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọ́run ni agbara, ki i ṣe láti da omi tútù sì wọn lọ́kàn tàbí láti bí ìdílé wo.

iii. Fi idi rẹ múlẹ̀ pé ko si ipenija kan tí o ga ju Ọlọ́run àti agbára Rẹ lọ, a kàn nílò láti ké pe E fún idasi; àti

iv. Ṣé àfihàn níní ìgbẹ́kẹ̀lé si I nínú ìpèsè Ọlọ́run àti ìfarahàn Rẹ ni akoko yòówù.

IFAARA

ORÍSUN Ẹ̀KỌ́: GENESISI 1:27-28; 2:18-25; 3:1; 16:1SWJ; 29:14B-30; 37:12-36; I SAMUEL 2:12SWJ; I KỌ́RÍŃTÌ 3:3; 6:18-19; 7:2-5; 10:13; ÉFÉSÙ 4:1SWJ; 5:22-33; HÉBÉRÙ 13:4.

Gbogbo ògo fún Ọlọ́run fún ohun gbogbo tí O ti gbin sínú wa ninu ọrọ Iye Rẹ, ní àwọn ọ̀sẹ̀ tó kọjá. Ki orúkọ Rẹ o di ayinlogo títí láé. Àmín.

Ni ọsẹ to kọjá, a parí ìjíròrò àkòrí náà, ÀWỌN OGUN ÀTI ÀWỌN TO Ń RÚ OGUN SÓKÈ WA, èyí tí o jẹ ẹ̀kọ́ tí o kẹ́yìn nínú ìsọri kejì (Àwọn Ogun Ìṣèlú àti Ọ̀rọ̀-Ajé). Ẹ̀kọ́ náà jẹ ìṣiloju fún wa láti mọ orísun ogun ni ọrùn àti ikilọ Ọlọ́run si awọn onigbagbọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ogun to ń pọ sii gẹ́gẹ́ bí àmì ìgbà ikẹyin, àti àwọn àbájáde rẹ fún igbe ayé Kristẹni. A gbàdúrà pé Ọrọ Rẹ yóò máa lágbára sii nínú wa. Àmín.

Ni ọsẹ yii àti èyí to ń bọ̀ a o bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ ni ìsọri kẹta (fifọ/pinpin yẹlẹyẹlẹ Eto Ìdílé). Ẹ̀kọ́ Kẹ̀sán niyii, ÀWỌN IPENIJA TO NII ṢE PẸ̀LÚ ÌDÍLÉ, O si wa lati kọ wa, fihan àti mú ní òye pé àwọn èdè aiyede àti ipenija jẹ ohun ti ko le sai ṣẹlẹ̀/wáyé nínú ilé wa, ṣùgbọ́n àwọn igbesẹ/ìdáhùn wa si iru àwọn ipenija àti èdè aiyede bẹẹ ń sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa, o si n safihan irú ẹni tí a jẹ, paapaa julọ tí o ní ṣe pẹ̀lú bí a ti dàgbà toju-u-bọ tó àti ibaṣepọ wa pẹ̀lú Ọlọ́run, ẹni tí o jẹ pé Òun nìkan ni Olufunni ni Ọna-Àbáyọ.

A gbàdúrà pé yóò mojuto àwọn ipenija tí àwọn ìdílé wa ń koju ni iru àkókò bí èyí ni orúkọ Jésù. Àmín. Ẹ kú àjọyọ àwọn ifọrọwerọ/itakurọsọ tí yóò seso rere!

IFAARA SI ÌPÍN KỌ̀Ọ̀KAN:

Èyí jẹ ẹ̀kọ́ ọ̀sẹ̀ méjì tí a pín si I àti II, tí a tún ṣe atunpin rẹ si A àti B.

ÌPÍN I: IDASILẸ ỌLỌ́RUN ÀKỌ́KỌ́.

Abala yii fi Ọlọ́run hàn gẹ́gẹ́bí Orísun àti Ẹnikan ṣoṣo tí o gbé ìdílé kalẹ tí O si n dari rẹ. Ọlọ́run ní abala yii ni a tún rí gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ó ni ìpinnu tí o gbé ìdílé kalẹ, fún ero, eto, àti ìpinnu tí araRẹ nìkan, tí a ko le e ba jẹ tàbí kí a yii padà. Nítorí náà, àwọn lọkọlaya gbọ́dọ̀ ṣe ohun gbogbo láti jẹ ki ìṣọ̀kan àti ifẹ wa ni ìdílé tàbí ilé. Tọkọtaya gbọ́dọ̀ wa ni ibaṣepọ lórí ilẹ̀ ayé ni ipo Ọlọ́run ni ayé, láti ṣojú Rẹ. A gbọ́dọ̀ pé Ọlọ́run si gbogbo ọrọ ti o ni ìṣe pẹ̀lú ìdílé, bí a ba n fẹ́ àṣeyọrí àti ayọ. Wíwà Jésù ni kana tí Gálílì ni o mú ayọ àwọn tọkọtaya padà wa (Jhn. 2:1swj).

ÌPÍN II: ÌDÍLÉ BẸ̀RẸ̀ SI I KOJU IPENIJA

Abala yii fihan pe àwọn ipenija wa nitootọ tí a ko sì le e sẹ wọn nínú ìdílé. Ipenija lè fi ara hàn ní onirunrun ọna, ṣùgbọ́n òtítọ́ ibẹ ni pé, agbára Ọlọ́run àti ìwà láàyè Rẹ nínú ìdílé ni yóò mú irú ipenija bẹẹ padà sí ẹri Ọlọ́run àti ìwà láàyè Rẹ nínú ìdílé ni yóò mú irú ipenija bẹẹ padà si ẹri láìsí iyèméjì (Jhn. 16:33). Gẹ́gẹ́ bí o ti jẹ pé gbogbo ìṣòro ni o ni okunfa, bákan náà, àwọn ọ̀nà àbáyọ a máa wà fún gbogbo ipenija inú ayé àti ti ìdílé, bí a ba pé Jésù Kristi láti jọba kí O sì gba gbogbo akoso ìdílé.

KOKO Ẹ̀KỌ́

I. ÌDÍLÉ: IDASILẸ ỌLỌ́RUN ÀKỌ́KỌ́

   A. ỌLỌ́RUN SAGBEKALẸ ÌDÍLÉ

   B. ERONGBA ỌLỌ́RUN FÚN ÌGBÉKALẸ ÌDÍLÉ

II. ÌDÍLÉ BẸ̀RẸ̀ SII KOJU IPENIJA

    A. ÀWỌN OKUNFA RẸ

    B. Ọ̀NÀ-ÀBÁYỌ

ITUPALẸ Ẹ̀KỌ́

I. ÌDÍLÉ: IDASILẸ ỌLỌ́RUN ÀKỌ́KỌ́ (Genesisi 1:27-28; 2:18-25; I Kọ́ríńtì 6:18-19; 7:2-5.

Ìdílé ni aringbungbun eto Ọlọ́run fún ìdùnnú àti ìtẹ́siwaju àwọn ọmọ Rẹ nínú ayé yii, ki O ba le mú eredi ayérayé ṣẹ fún ìran ènìyàn. A máa ṣe iranlọwọ láti yanjú ìṣòro àìrí ẹni ba kẹgbẹ, aitẹsiwaju ìran ènìyàn nítorí aibi sii, àti nípasẹ̀ èyí fi òpin si ìpinnu èṣù láti ba eto Ọlọ́run fún ènìyàn jẹ nípasẹ̀ àgbèrè.

A. ỌLỌ́RUN ṢÀGBEKALẸ ÌDÍLÉ (Gen. 2:18-25)

Nítorí náà ni ọkùnrin yóò ṣe máa fi bàbà òun ìyá rẹ silẹ, yóò sì fi ara mọ aya rẹ; wọn o si di ara kan (ẹsẹ 24).

i. Idasilẹ tí Ọlọ́run kọ́kọ́ gbékalẹ fún ibaṣepọ/ibasọrọpọ ènìyàn ni ìdílé. Níwọ̀n bí o ti jẹ pé Ọlọ́run da ènìyàn ni ẹda tí o le bára wọn kẹgbẹ pọ (wo 3:8a). O jẹ àárín gbùngbùn eto Ọlọ́run fún ìdùnnú àti ìtẹ́siwaju àwọn ọmọ Ọlọ́run.

ii. Ẹsẹ 18-23: Lẹ́yìn tí o ti da ènìyàn ni akọ àti abo, lakọkọ na (1:27), Ọlọ́run mú obìnrin náà jáde wa lẹ́yìn-o-rẹyìn (Kii ṣe ọkùnrin miran tàbí ẹranko; kíyèsii ìgbéyàwó laarin ọkùnrin sí ọkùnrin tàbí obìnrin sí obìnrin, àwọn to n ba ẹranko dapọ), ní àkókò tí o tọ́ (ẹsẹ 16-22), O si mú un wa si ọdọ ọkùnrin náà (ẹsẹ 22b, 23). Ọlọ́run ṣi ń fún ní ní ọkọ/aya tí o dara nígbà tí a ba béèrè lọ́wọ́ Rẹ.

iii. Ẹsẹ 22: Ibaṣepọ timọ̀timọ̀ tí o wa laarin ọkàn àti egungun ìhà lágbára/ga púpọ̀. Bákan náà, egungun ìhà ń dáàbò bo/ṣe ìpamọ́ ọkàn tí o ń fún un ní iye. Nìtori Ọlọ́run ń retí ibadọrẹ/ibaṣepọ tí o jẹ timọ̀timọ̀ julọ laarin ọkùnrin náà àti ìyàwó rẹ.

iv. Ẹsẹ 23: Ìgbéyàwó jẹ mimọ/ohun iyasọtọ nígbà tí àwọn méjèèjì (ọkọ/aya) ba fọwọ́si tí wọn sí bù ọlá fún un, nínú ìwà-mímọ (Heb. 13:4), nítorí o n faaye gba ibaṣepọ pẹ̀lú Ọlọ́run, ẹni tí o gbé e kalẹ, ẹni tí o ro àwọn ọkùnrin àti obìnrin ni agbara fún onírúurú ojúṣe/ìṣẹ́ fún àfojúsùn kan náà --- bíbu ọlá fún Òun nìkan. Ko si ẹ̀yà kan (ọkùnrin tàbí obìnrin) tí o dara ju ọkàn lọ. Síbẹ̀, O ti fún ọkùnrin ní ipò jíjẹ olórí nínú ilé (wo I Kor. 11:8swj).

v. Ẹsẹ 24: "Fi (baba àti ìyá) silẹ, famọ, yóò sì di ara kan" túmọ̀ sì jíjẹ olotitọ pátápátá, wíwà ní ìṣọ̀kan pátápátá, ṣíṣe alájọpín pátápátá àti wíwà ní timọ̀timọ̀ láìsí àwọn gbedeke/ọ̀tẹ̀. Àwọn ìgbéyàwó tí o ba n lépa láti duroore gbọ́dọ̀ ni àwọn ohun wọnyii. Ìyẹn ni odiwọn Ọlọ́run!

vi. Ẹsẹ 25: Àwọn méjèèjì sí wa ni ihoho... wọn ko si tijú. Ìgbéyàwó tí a ba kọ sórí ipilẹ Kristi gbọ́dọ̀ máa fi ìwà jíjẹ olotitọ pátápátá si ìṣe. Tú àṣírí ìdílé rẹ fún Ọlọ́run, láti ṣi ojú opo ibára-ẹni-sọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú Rẹ ati pẹ̀lú ara yín silẹ. Àwọn ìgbéyàwó oníwà-bí-Ọlọ́run kii pamọ sínú àwọn àṣírí tí ko nitumọ.

vii. Ìgbéyàwó jẹ májẹ̀mú kii ṣe eto ibagbepọ lásán. O jẹ ifaraji tí a ko lee yipada tí o wa fún gbogbo ìgbà tí ènìyàn ba wa láàyè. Àdéhùn kí àdéhùn ni ènìyàn le yẹ nígbà yowu, ní pàtàkì nígbà tí èyíkéyìí nínú àwọn tí o ṣe àdéhùn bẹẹ ba tàpá si ofin ibagbepọ wọn. Ní idakẹjẹ ẹwẹ, ìgbéyàwó jẹ májẹ̀mú laarin Ọlọ́run àti àwọn tọkọtaya tí wọn ń da májẹ̀mú náà nítorí pé ohun kan ṣoṣo tí o le e bá májẹ̀mú náà jẹ ní, ikú. Ki i ṣe ikọsilẹ, iyapa, tàbí ìdí miran, bí o ti wu ki a rí pé o ba òfin mu tó lonii; ni o le e ba májẹ̀mú ìgbéyàwó jẹ àti ojú tí Ọlọ́run, Ẹlẹ́daa, Orísun ati olùgbéro eto ìgbéyàwó fi wo o.

B. ERONGBA ỌLỌ́RUN FÚN IGBEKALẸ ÌDÍLÉ (Gen. 1:27-28; 2:18; I Kor. 6:18-19; 7:2-5).

Olúwa Ọlọ́run sì wí pé, ko dara ki ọkùnrin náà ó nìkan máa gbé, Èmi o ṣe oluranlọwọ tí ó dàbí rẹ fún un (Gen. 2:18).

i. Ọlọ́run elerongba náà ko ṣàgbékalẹ ìdílé láìsí ìpinnu, láìsí èrò tàbí lairo tẹ́lẹ̀. O ni àwọn erongba ọkàn Rẹ fún ṣíṣágbekalẹ ilé/ìdílé.

ii. 2:18: Fún Ádámù láti máa danikan wa. Ọlọ́run ti rí ìwúlò fún ajumọkẹgbẹpọ, níwọ̀n bí ó ti jẹ pe Oun yoo da ènìyàn ni ẹda tí o le kẹgbẹpọ/ronú fúnrarẹ. O mọ pe ko nii dára kí ọkùnrin o danikan wa, èyí ni eredi tí O fi dá wọn ní akọ àti abo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹpẹ. Didanikan wa maa n pani (Oniw. 4:8-11).

iii. Ádámù nílò oluranlọwọ tí o dabi rẹ (wíwà ní ìbámu pẹ̀lú ara wọn) èyí tí ko lè rí laarin awọn ẹda miran (ẹsẹ 19-20). Ọlọ́run mú ìyàwó náà wá láti ṣe ìtọ́jú ìyẹn. Ǹjẹ́ ko ha jẹ ohun ti ó panilẹrin tí ko si mọgbọn wa fún ẹnikẹ́ni láti fẹ ẹranko gẹ́gẹ́ bí ọkọ/aya bi? (Rom. 1:28).

iv. Ọlọ́run ti fi ọkùnrin náà sínú ọgbà Édẹ́nì láti maa ro o, àti láti máa ṣọọ (ẹsẹ 15). Ọkùnrin nílò oluranlọwọ láti mu ìṣẹ́ rọrùn. Gẹ́gẹ́ bí o ti jẹ pe ẹni méjì máa ń san ju ẹni kan lọ. Ọkùnrin náà àti ìyàwó rẹ gbọ́dọ̀ jẹ alabakẹgbẹ́-pọ; àwọn ẹni tí wọn ń tú ara wọn nínú àti oluranlọwọ ara wọn ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn (Oniwa. 4:9).

v. I Kor. 6:18-19; 7:2-5: Ọlọ́run ṣàgbékalẹ ìgbéyàwó àti ìdílé láti moribọ nínú àgbèrè àti àwọn ìwà aitọ miran laarin awọn ọdọ àti àwọn miran.

vi. Gen. 1:27, 28: Ọlọ́run ní ìpinnu pé ìdílé nípasẹ̀ gíga julọ Rẹ, iranlọwọ àti ẹ̀bùn Rẹ, yóò bí àwọn ọmọ, yóò sì ṣe igbedide àwọn ìran, to ń ṣafihan ògo Ọlọ́run ni gbogbo ayé (wo 18:19). Síbẹ̀, aitete rí ọmọ bí ko yẹ kí ó tú ìgbéyàwó ka. Kẹ́kọ̀ọ́ lára Sakaraya àti Èlísábẹ́tì. A gbàdúrà pé Ọlọ́run yóò gbọ àdúrà àwọn ìdílé to ń woju Ọlọ́run fún èso inú ni orúkọ Jésù. Àmín.

vii. Ọlọ́run tún ní erongba pé kí ìdílé o jẹ ohun-èlò ìtànkalẹ ihinrere Rẹ (Mat. 28:18swj; Mi. 16:15), gẹgẹ bii Ákúílà àti Priskilla, àwọn ẹni tí o ṣíṣẹ débi pé wọn ní ìjọ nínú ilé wọn (Rom. 16:3-5).

viii.Ati ọkùnrin àti obìnrin ni a da láti jẹ oluranlọwọ fún ara wọn nínú igbekalẹ Ọlọ́run (ìdílé). Ìdílé jẹ orísun àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run ń gba pín ìbùkún àti ìfihàn, èyí tí O gbé kalẹ fún ibaṣepọ tààrà pẹ̀lú ẹni kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé. A ko nii ṣi anfaani yìí àti ìdí abájọ rẹ lo, ní orúkọ Jésù.

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÍ A RÍ KỌ

1. Ìdílé jẹ agbekalẹ Ọlọ́run ti a gbọ́dọ̀ fi ìtara pamọ/dáàbò bo fún Un; a ko gbọ́dọ̀ gbé àwọn ohun aitọ wọnú rẹ.

2. Láti gba èyí tí o dara julọ Ọlọ́run nínú ìgbéyàwó, mọ èrò gba Ọlọ́run fún ṣíṣágbekalẹ ìdílé.

ÌṢẸ́ ṢÍṢE

Ṣàlàyé àbọ̀ gbólóhùn náà, "Fi silẹ, fa mọ àti di ara kan"?

ÌDÁHÙN TÍ A DÁBÀÁ FÚN ÌṢẸ́ ṢÍṢE

Ọ̀rọ̀ yii "Fi silẹ, dapọ kí ẹ si ni arakan" túmọ̀ si:

i. Fífi silẹ nihin in ko túmọ̀ sí kíkọ àwọn òbí wa silẹ àwọn tí o tọ́ wa ti wọn si tọju wa dàgbà kí a to le dára pọ mọ olufẹ ọkàn wa (ọkọ tàbí aya), ṣùgbọ́n a ko gbọ́dọ̀ jẹ ki wọn jẹ gàba lórí ìdílé wa. Rántí, a sì ni àwọn ojúṣe nípa ti ẹ̀mí, tí ara, tí ọkàn, tí ibaṣepọ sí wọn niwọn ìgbà tí wọ́n ba wa láàyè. Fífi silẹ tún túmọ̀ si láti di ominira, kí a ma ṣe rọgbọku oúnjẹ, owo, ìpinnu ṣíṣe àti bẹẹbẹẹ lọ tí àwọn òbí wa.

ii. Didapọ mọ túmọ̀ si síso mọ pinpin, tọkàntọkàn àti ní òdodo mọ ẹnikan. O le jẹ wíwà ni sísun mọ ẹlòmíràn bí ọkùnrin si obìnrin tàbí obìnrin si ọkùnrin láti ìdílé tí o yatọ láti lè gbé papọ ni ìgbéyàwó títí ikú yóò fi ya wọn. Èyí túmọ̀ sí pé ọkùnrin àti ìyàwó rẹ gbọ́dọ̀ wa papọ, le mọ ara wọn, kí wọn ma ṣeé pin níyà àti pípa ohun ìní wọn papọ ìyẹn ni owo, ero ọkàn, tí ibaṣepọ àti nípa ti ara, abbl.

iii. Láti di ara kan túmọ̀ sí pé láti wa ni ìṣọ̀kan ni ìpinnu ṣíṣe, ọrọ, eto, erongba, iṣẹ isin sì Ọlọ́run, fífúnni, ọmọ bibi àti itọju. Sísun papọ, jijẹun papọ, wiwẹ papọ, sisọrọ tàbí jijiroro papọ, rìnrìn àti jíjókòó papọ, abbl.

Fun ifisilẹ àti idapọ tí o dán mọran, takọtaya gbọ́dọ̀:

* Pa àwọn ààlà ti ó tọ;

* Ni àwọn gbedeke ni wọn ti ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn; àti

* Ṣe àfihàn ìṣọ̀kan nínú ohun gbogbo títí ikú yóò fi ya wọn.

Post a Comment

0 Comments