Subscribe Us

header ads

Omi Iye Naa (CAC Living Water) - Wa Okunrin Naa Ti O Le Sinmile

Omi Iye Naa (CAC Living Water) October 15, 2021 - Wa Okunrin Naa Ti O Le Sinmile

Omi Iye Naa (CAC Living Water) October 15, 2021 - Wa Okunrin Naa Ti O Le Sinmile
(Ayajo Ojo Awon Obinrin Ti Won Wa Ni Igberiko L'agbaye).

Akori: Wa Okunrin Naa Ti O Le Sinmile.

Ka Genesisi 2:21-24

Akosori: Oluwa Olorun si fi egungun iha ti o mu ni iha okunrin naa mo obinrin, O si mu un to okunrin naa wa (Genesisi 2:22).

ITUPALE

Laiwo ti igbe/ikede awon ajo to n ri si ominira awon obinrin ti o gba ibi gbogbo kan, o je ohun ti ko se e se pe awon obinrin je ohun -elo elege si okunrin. Kii se eesi bi kose ohun ti o ti wa nikale lati seto iru oro yii ni ojo oni tii se Ayajo Ojo Awon Obinrin Ti O Wa Ni Igberiko.

Ni iseda, Olorun yo egungun kan lati iha okunrin to sun oorun ijika naa, pelu re, O da obinrin naa. E je ki a wo o bayii. Niti eniyan, sisakawe okunrin ti a da lati ibere pepe lati inu erupe ile pelu obinrin ti a da lati inu egungun kan lati iha okunrin naa ni ti agbara/okun le ma mogbon wa. Niti eniyan, eto mimu ki egungun iha naa o fe sii, le mu ki eda ti a da nipase re, obinrin naa, o je alailagbara bi okunrin naa. Abajo ti a fi toka si obinrin bi ohun elege (I Pet. 3:7)

Jije alailagbara nipa ti iseda tumosi pe iyawo naa yoo ni lati sinmile agbara okunrin (oko) naa. Bakan naa, o ti di pe Ife iyawo naa yoo maa fa si oko re nikan, eni ti yoo maa je olori/alakoso fun un (3:16). Oun ti o tumo si ni pe gbogbo obinrin nilati wa okunrin kansoso ti Olorun yan, eni ti o le sinmile ni ona ti Olorun.

A ti ri okunrin naa ko le rorun. Arabinrin naa nilo oore-ofe ati ogbon Olorun lati mo arakunrin ti a n soro nipa re yii yato laarin ogooro okunrin to wa laye. Nitori naa o nilo lati wa ni isokan pelu Kristi nipase iyilokan pada, ki Emi Mimo Re o le dari ni ona ti o to (wo Rom. 8:14). Mase yan tabi rin oju ona naa ni ona tire; o lewu lati danikan se e ( wo Owe 16:25).

Awon Koko Adura:

1. Jesu Oluwa, ran mi lowo lati mase se asise ninu awon ohun ti n o maa yan/ipinnu ti n o maase laye.

2. Gbadura fun awon arakunrin/arabinrin ti ko tii laya/loko ni awon ijo wa fun suuru lati duro de Olorun fun eyi to dara julo Re fun won ni ti igbeyawo, idile ati ojo iwaju won.

3. Gbadura pe ki Olorun o fi aanu ati oore-ofe ran awon arakunrin/arabinrin ti won ko tii laya/loko ti won je Kristieni ti won si ti wonu ibadorepo pelu awon afesona ti ko to ati alaiwa-bi-Olorun.

Afikun Ibi Kika Fun Oni: Isaiah 30:14 - 33:14; Filipi 4:17 - 4:23; Kol. 1:1 - 1:15.

Post a Comment

0 Comments